BESALELI ati Oholiabu yio si ṣiṣẹ, ati olukuluku ọlọgbọ́n inu, ninu ẹniti OLUWA fi ọgbọn ati oyé si, lati mọ̀ bi a ti ṣiṣẹ onirũru iṣẹ ìsin ibi mimọ́ na, gẹgẹ bi gbogbo ohun ti OLUWA ti palaṣẹ.