1. NIGBANA li awa pada, a si lọ soke li ọ̀na Baṣani: Ogu ọba Baṣani si jade si wa, on ati gbogbo awọn enia rẹ̀, fun ìja ni Edrei.
2. OLUWA si wi fun mi pe, Máṣe bẹ̀ru rẹ̀: nitoripe emi ti fi on, ati gbogbo awọn enia rẹ̀, ati ilẹ rẹ̀, le ọ lọwọ; iwọ o si ṣe si i bi iwọ ti ṣe si Sihoni ọba ọmọ Amori, ti ngbé Heṣboni.
3. Bẹ̃ni OLUWA Ọlọrun wa fi Ogu, ọba Baṣani, ati gbogbo awọn enia rẹ̀, lé wa lọwọ pẹlu: awa si kọlù u titi kò si kù ẹnikan silẹ fun u.
4. Awa si kó gbogbo ilu rẹ̀ ni ìgba na; kò sí ilu kan ti awa kò gbà lọwọ wọn; ọgọta ilu, gbogbo ẹkùn Argobu, ilẹ ọba Ogu ni Baṣani.
5. Gbogbo ilu wọnyi li a mọ odi giga si pẹlu ibode, ati idabu-ẹ̀kun; laikà ọ̀pọlọpọ ilu alailodi.
6. Awa si run wọn patapata, bi awa ti ṣe si Sihoni ọba Heṣboni, ni rirun awọn ọkunrin, obinrin, ati awọn ọmọ wẹ́wẹ patapata, ni ilu na gbogbo.
7. Ṣugbọn gbogbo ohunọ̀sin, ati ikogun ilu wọnni li awa kó ni ikogun fun ara wa.