18. Egún ni fun ọmọ inu rẹ, ati eso ilẹ rẹ, ibisi malu rẹ, ati ọmọ agutan rẹ.
19. Egún ni fun ọ nigbati iwọ ba wọle, egún si ni fun ọ nigbati iwọ ba jade.
20. OLUWA yio si rán egún, idamu, ati ibawi sori rẹ, ninu gbogbo ohun ti iwọ ba fi ọwọ́ rẹ lé ni ṣiṣe, titi a o fi run ọ, ati titi iwọ o fi ṣegbé kánkán; nitori buburu iṣe rẹ, nipa eyiti iwọ fi kọ̀ mi silẹ.
21. OLUWA yio si mu ajakalẹ-àrun lẹ̀ mọ́ ọ, titi on o fi run ọ kuro lori ilẹ na, nibiti iwọ nlọ lati gbà a.
22. OLUWA yio si fi àrun-igbẹ kọlù ọ, ati ibà, ati igbona, ati ijoni nla, ati idà, ati ìrẹdanu, ati imuwodu; nwọn o si lepa rẹ titi iwọ o fi run.
23. Ọrun rẹ ti mbẹ lori rẹ yio jẹ́ idẹ, ilẹ ti mbẹ nisalẹ rẹ yio si jẹ́ irin.
24. OLUWA yio sọ òjo ilẹ rẹ di ẹ̀tù ati ekuru: lati ọrun ni yio ti ma sọkalẹ si ọ, titi iwọ o fi run.
25. OLUWA yio si mu ọ di ẹni ikọlù niwaju awọn ọtá rẹ: iwọ o jade tọ̀ wọn lọ li ọ̀na kan, iwọ o si sá niwaju wọn li ọ̀na meje: a o si ṣí ọ kiri gbogbo ijọba aiye.
26. Okú rẹ yio si jẹ́ onjẹ fun gbogbo ẹiyẹ oju-ọ̀run, ati fun ẹranko aiye, kò si sí ẹniti yio lé wọn kuro.
27. OLUWA yio si fi õwo Egipti lù ọ, ati iyọdi, ati ekúru, ati ẹyi-ara, eyiti a ki yio le wòsan.
28. OLUWA yio fi isinwin kọlù ọ, ati ifọju, ati ipàiya:
29. Iwọ o si ma fi ọwọ́ talẹ li ọsán gangan, bi afọju ti ifi ọwọ́ talẹ ninu òkunkun, iwọ ki yio si ri rere ninu ọ̀na rẹ: ẹni inilara ṣá ati ẹni kikó li ọjọ́ gbogbo ni iwọ o jẹ́, ki o si sí ẹniti o gbà ọ.
30. Iwọ o fẹ́ iyawo, ọkunrin miran ni yio si bá a dàpọ: iwọ o kọ ile, iwọ ki yio si gbé inu rẹ̀: iwọ o gbìn ọgbà-àjara, iwọ ki yio si ká eso rẹ̀.