OLUWA yio si rán egún, idamu, ati ibawi sori rẹ, ninu gbogbo ohun ti iwọ ba fi ọwọ́ rẹ lé ni ṣiṣe, titi a o fi run ọ, ati titi iwọ o fi ṣegbé kánkán; nitori buburu iṣe rẹ, nipa eyiti iwọ fi kọ̀ mi silẹ.