10. Gbogbo enia aiye yio si ri pe orukọ OLUWA li a fi npè ọ; nwọn o si ma bẹ̀ru rẹ.
11. OLUWA yio si sọ ọ di pupọ̀ fun rere, ninu ọmọ inu rẹ, ati ninu irú ohunọ̀sin rẹ, ati ninu eso ilẹ rẹ, ni ilẹ ti OLUWA ti bura fun awọn baba rẹ lati fun ọ.
12. OLUWA yio ṣí iṣura rere rẹ̀ silẹ fun ọ, ọrun lati rọ̀jo si ilẹ rẹ li akokò rẹ̀, ati lati busi iṣẹ ọwọ́ rẹ gbogbo: iwọ o si ma wín orilẹ-ède pupọ̀, iwọ ki yio si tọrọ.
13. OLUWA yio si fi ọ ṣe ori, ki yio si ṣe ìru; iwọ o si ma leke ṣá, iwọ ki yio si jẹ́ ẹni ẹhin; bi o ba fetisi aṣẹ OLUWA Ọlọrun rẹ, ti mo pa fun ọ li oni, lati ma kiyesi on ati ma ṣe wọn;
14. Iwọ kò si gbọdọ yà kuro ninu gbogbo ọ̀rọ ti mo palaṣẹ fun nyin li oni, si ọtún, tabi si òsi, lati tọ̀ ọlọrun miran lẹhin lati sìn wọn.
15. Yio si ṣe, bi iwọ kò ba fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma kiyesi ati ṣe gbogbo aṣẹ rẹ̀ ati ìlana rẹ̀ ti mo filelẹ fun ọ li oni; njẹ gbogbo egún wọnyi yio ṣẹ sori rẹ, yio si bá ọ.
16. Egún ni fun ọ ni ilu, egún ni fun ọ li oko.
17. Egún ni fun agbọ̀n rẹ ati ọpọ́n-ipò-àkara rẹ.
18. Egún ni fun ọmọ inu rẹ, ati eso ilẹ rẹ, ibisi malu rẹ, ati ọmọ agutan rẹ.
19. Egún ni fun ọ nigbati iwọ ba wọle, egún si ni fun ọ nigbati iwọ ba jade.
20. OLUWA yio si rán egún, idamu, ati ibawi sori rẹ, ninu gbogbo ohun ti iwọ ba fi ọwọ́ rẹ lé ni ṣiṣe, titi a o fi run ọ, ati titi iwọ o fi ṣegbé kánkán; nitori buburu iṣe rẹ, nipa eyiti iwọ fi kọ̀ mi silẹ.
21. OLUWA yio si mu ajakalẹ-àrun lẹ̀ mọ́ ọ, titi on o fi run ọ kuro lori ilẹ na, nibiti iwọ nlọ lati gbà a.