1. NIGBANA li awa pada, awa si mú ọ̀na wa pọ̀n lọ si aginjù li ọ̀na Okun Pupa, bi OLUWA ti sọ fun mi: awa si yi òke Seiri ká li ọjọ́ pupọ̀.
2. OLUWA si sọ fun mi pe,
3. Ẹnyin ti yi òke yi ká pẹ to: ẹ pada si ìha ariwa.
4. Ki iwọ ki o si fi aṣẹ fun awọn enia, pe, Ẹnyin o là ẹkùn awọn arakunrin nyin kọja, awọn ọmọ Esau ti ngbé Seiri; ẹ̀ru nyin yio bà wọn: nitorina ẹ ṣọra nyin gidigidi:
5. Ẹ máṣe bá wọn jà; nitoripe emi ki yio fun nyin ninu ilẹ wọn, ani to bi ẹsẹ̀ kan: nitoriti mo ti fi òke Seiri fun Esau ni iní.
6. Owo ni ki ẹnyin fi rà onjẹ lọwọ wọn, ti ẹnyin o jẹ; owo ni ki ẹnyin si fi rà omi lọwọ wọn pẹlu, ti ẹnyin o mu.
7. Nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ ti bukún ọ ninu iṣẹ ọwọ́ rẹ gbogbo: o ti mọ̀ ìrin rẹ li aginjù nla yi: li ogoji ọdún yi OLUWA Ọlọrun rẹ ti mbẹ pẹlu rẹ; ọdá ohun kan kò dá ọ.
8. Nigbati awa si kọja lẹba awọn arakunrin wa awọn ọmọ Esau, ti ngbé Seiri, li ọ̀na pẹtẹlẹ̀ lati Elati wá, ati lati Esion-geberi wá, awa pada, awa si kọja li ọ̀na aginjù Moabu.
9. OLUWA si wi fun mi pe, Ẹ máṣe bi awọn ara Moabu ninu, bẹ̃ni ki ẹ máṣe fi ogun jà wọn: nitoripe emi ki yio fi ninu ilẹ rẹ̀ fun ọ ni iní; nitoriti mo ti fi Ari fun awọn ọmọ Lotu ni iní.
10. (Awọn Emimu ti ngbé inu rẹ̀ ni ìgba atijọ rí, awọn enia nla, nwọn si pọ̀, nwọn si sigbọnlẹ, bi awọn ọmọ Anaki:
11. Ti a nkà kún awọn omirán, bi awọn ọmọ Anaki; ṣugbọn awọn ara Moabu a ma pè wọn ni Emimu.
12. Awọn ọmọ Hori pẹlu ti ngbé Seiri rí, ṣugbọn awọn ọmọ Esau tẹle wọn, nwọn si run wọn kuro niwaju wọn, nwọn si ngbé ibẹ̀ ni ipò wọn; gẹgẹ bi Israeli ti ṣe si ilẹ-iní rẹ̀, ti OLUWA fi fun wọn.)