7. Gideoni si wipe, Nitorina nigbati OLUWA ba fi Seba ati Salmunna lé mi lọwọ, nigbana li emi o fi ẹgún ijù, ati oṣuṣu yà ẹran ara nyin.
8. On si gòke lati ibẹ̀ lọ si Penueli, o si sọ fun wọn bẹ̃ gẹgẹ: awọn ọkunrin Penueli si da a lohùn gẹgẹ bi awọn ara Sukkotu si ti da a lohùn.
9. On si wi fun awọn ọkunrin Penueli pẹlu pe, Nigbati mo ba pada dé li alafia, emi o wó ile-ẹṣọ́ yi lulẹ̀.
10. Njẹ Seba ati Salmunna wà ni Karkori, ogun wọn si wà pẹlu wọn, o to ìwọn ẹdẹgbajọ ọkunrin, iye awọn ti o kù ninu gbogbo ogun awọn ọmọ ìha ìla-õrùn: nitoripe ẹgba ọgọta ọkunrin ti o lo idà ti ṣubu.
11. Gideoni si gbà ọ̀na awọn ti ngbé inú agọ́ ni ìha ìla-õrùn Noba ati Jogbeha gòke lọ, o si kọlù ogun na; nitoriti ogun na ti sọranù.
12. Seba ati Salmunna si sá; on si lepa wọn; o si mù awọn ọba Midiani mejeji na, Seba ati Salmunna, o si damu gbogbo ogun na.
13. Gideoni ọmọ Joaṣi si pada lẹhin ogun na, ni ibi ati gòke Heresi.
14. O si mú ọmọkunrin kan ninu awọn ọkunrin Sukkotu, o si bère lọwọ rẹ̀: on si ṣe apẹrẹ awọn ọmọ-alade Sukkotu fun u, ati awọn àgba ti o wà nibẹ̀, mẹtadilọgọrin ọkunrin.
15. On si tọ̀ awọn ọkunrin Sukkotu na wá, o si wi fun wọn pe, Wò Seba ati Salmunna, nitori awọn ẹniti ẹnyin fi gàn mi pe, Ọwọ́ rẹ ha ti tẹ Seba ati Salmunna na, ti awa o fi fun awọn ọkunrin rẹ ti ãrẹ mu li onjẹ?
16. On si mú awọn àgbagba ilu na, ati ẹgún ijù ati oṣuṣu, o si fi kọ́ awọn ọkunrin Sukkotu li ọgbọ́n.
17. On si wó ile-ẹṣọ́ Penueli, o si pa awọn ọkunrin ilu na.
18. Nigbana li o sọ fun Seba ati Salmunna, wipe, Irú ọkunrin wo li awọn ẹniti ẹnyin pa ni Taboru? Nwọn si dahùn, Bi iwọ ti ri, bẹ̃ni nwọn ri; olukuluku nwọn dabi awọn ọmọ ọba.
19. On si wipe, Arakunrin mi ni nwọn, ọmọ iya mi ni nwọn iṣe: bi OLUWA ti wà, ibaṣepe ẹnyin da wọn si, emi kì ba ti pa nyin.
20. On si wi fun Jeteri arẹmọ rẹ̀ pe, Dide, ki o si pa wọn. Ṣugbọn ọmọkunrin na kò fà idà rẹ̀ yọ: nitori ẹ̀ru bà a, nitoripe ọmọde ni iṣe.
21. Nigbana ni Seba ati Salmunna wipe, Iwọ dide, ki o si kọlù wa: nitoripe bi ọkunrin ti ri, bẹ̃li agbara rẹ̀ ri. Gideoni si dide, o si pa Seba ati Salmunna, o si bọ́ ohun ọṣọ́ wọnni kuro li ọrùn ibakasiẹ wọn.
22. Nigbana li awọn ọkunrin Israeli wi fun Gideoni pe, Iwọ ma ṣe olori wa, iwọ, ati ọmọ rẹ, ati ọmọ ọmọ rẹ pẹlu: nitoripe o gbà wa lọwọ awọn ara Midiani.
23. Gideoni si wi fun wọn pe, Emi ki yio ṣe olori nyin, bẹ̃ni ọmọ mi ki yio ṣe olori nyin: OLUWA ni yio ma ṣe alaṣẹ nyin.
24. Gideoni si wi fun wọn pe, Emi o bère nkan lọwọ nyin, pe ki olukuluku nyin ki o le fi oruka-etí ti mbẹ ninu ikogun rẹ̀ fun mi. (Nitoriti nwọn ní oruka-etí ti wurà, nitoripe ọmọ Iṣmaeli ni nwọn iṣe.)