A. Oni 8:29-35 Yorùbá Bibeli (YCE)

29. Jerubbaali ọmọ Joaṣi si lọ o si ngbe ile rẹ̀.

30. Gideoni si ní ãdọrin ọmọkunrin ti o bi fun ara rẹ̀: nitoripe o lí obinrin pupọ̀.

31. Ale rẹ̀ ti o wà ni Ṣekemu, on pẹlu bi ọmọkunrin kan fun u, orukọ ẹniti a npè ni Abimeleki.

32. Gideoni ọmọ Joaṣi si kú li ọjọ́ ogbó, a si sin i si ibojì Joaṣi baba rẹ̀, ni Ofra ti awọn Abieseri.

33. O si ṣe, lojukanna ti Gideoni kú, li awọn ọmọ Israeli pada, nwọn si ṣe panṣaga tọ̀ Baalimu lọ, nwọn si fi Baaliberiti ṣe oriṣa wọn.

34. Awọn ọmọ Israeli kò si ranti OLUWA Ọlọrun wọn, ẹniti o gbà wọn lọwọ gbogbo awọn ọtá wọn ni ìha gbogbo:

35. Bẹ̃ni nwọn kò si ṣe ore fun ile Jerubbaali, ti iṣe Gideoni, gẹgẹ bi gbogbo ire ti o ti ṣe fun Israeli.

A. Oni 8