A. Oni 8:14-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. O si mú ọmọkunrin kan ninu awọn ọkunrin Sukkotu, o si bère lọwọ rẹ̀: on si ṣe apẹrẹ awọn ọmọ-alade Sukkotu fun u, ati awọn àgba ti o wà nibẹ̀, mẹtadilọgọrin ọkunrin.

15. On si tọ̀ awọn ọkunrin Sukkotu na wá, o si wi fun wọn pe, Wò Seba ati Salmunna, nitori awọn ẹniti ẹnyin fi gàn mi pe, Ọwọ́ rẹ ha ti tẹ Seba ati Salmunna na, ti awa o fi fun awọn ọkunrin rẹ ti ãrẹ mu li onjẹ?

16. On si mú awọn àgbagba ilu na, ati ẹgún ijù ati oṣuṣu, o si fi kọ́ awọn ọkunrin Sukkotu li ọgbọ́n.

17. On si wó ile-ẹṣọ́ Penueli, o si pa awọn ọkunrin ilu na.

18. Nigbana li o sọ fun Seba ati Salmunna, wipe, Irú ọkunrin wo li awọn ẹniti ẹnyin pa ni Taboru? Nwọn si dahùn, Bi iwọ ti ri, bẹ̃ni nwọn ri; olukuluku nwọn dabi awọn ọmọ ọba.

19. On si wipe, Arakunrin mi ni nwọn, ọmọ iya mi ni nwọn iṣe: bi OLUWA ti wà, ibaṣepe ẹnyin da wọn si, emi kì ba ti pa nyin.

20. On si wi fun Jeteri arẹmọ rẹ̀ pe, Dide, ki o si pa wọn. Ṣugbọn ọmọkunrin na kò fà idà rẹ̀ yọ: nitori ẹ̀ru bà a, nitoripe ọmọde ni iṣe.

21. Nigbana ni Seba ati Salmunna wipe, Iwọ dide, ki o si kọlù wa: nitoripe bi ọkunrin ti ri, bẹ̃li agbara rẹ̀ ri. Gideoni si dide, o si pa Seba ati Salmunna, o si bọ́ ohun ọṣọ́ wọnni kuro li ọrùn ibakasiẹ wọn.

22. Nigbana li awọn ọkunrin Israeli wi fun Gideoni pe, Iwọ ma ṣe olori wa, iwọ, ati ọmọ rẹ, ati ọmọ ọmọ rẹ pẹlu: nitoripe o gbà wa lọwọ awọn ara Midiani.

A. Oni 8