Tẹsalonika Kinni 5:4-14 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Ẹ̀yin ará, ẹ̀yin kò sí ninu òkùnkùn ní tiyín, tí ọjọ́ náà yóo fi dé ba yín bí ìgbà tí olè bá dé.

5. Nítorí ọmọ ìmọ́lẹ̀ ni gbogbo yín; ọmọ tí a bí ní àkókò tí ojú ti là sí òtítọ́, ẹ kì í ṣe àwọn tí a bí ní àkókò àìmọ̀kan; ẹ kì í ṣe ọmọ òkùnkùn.

6. Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí á máa sùn bí àwọn yòókù, ṣugbọn ẹ jẹ́ kí á máa ṣọ́nà, kí á sì máa ṣọ́ra.

7. Nítorí òru ni àwọn tí ń sùn ń sùn, òru sì ni àwọn tí ó ń mutí ń mutí.

8. Ṣugbọn ní tiwa, ojúmọmọ ni iṣẹ́ tiwa, nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á farabalẹ̀, kí á wọ aṣọ ìgbàyà igbagbọ ati ìfẹ́, kí á dé fìlà ìrètí ìgbàlà.

9. Nítorí Ọlọrun kò pè wá sinu ibinu, ṣugbọn sí inú ìgbàlà nípasẹ̀ Oluwa wa Jesu Kristi,

10. tí ó kú nítorí tiwa, ni ó pè wá sí, pé bí à ń ṣọ́nà ni, tabi a sùn ni, kí á jọ wà láàyè pẹlu rẹ̀.

11. Nítorí náà, ẹ máa tu ara yín ninu, kí ẹ sì máa fún ara yín ní ìwúrí, bí ẹ ti ń ṣe.

12. Ẹ̀yin ará, à ń bẹ̀ yín pé kí ẹ máa bu ọlá fún àwọn tí ń ṣe làálàá láàrin yín, tí wọn ń darí yín nípa ti Oluwa, tí wọn ń gbà yín níyànjú.

13. Ẹ máa fi ìfẹ́ yẹ́ wọn sí gidigidi nítorí iṣẹ́ wọn. Ẹ máa wà ní alaafia láàrin ara yín.

14. Ará, à ń rọ̀ yín pé kí ẹ máa gba àwọn tí ń ṣe ìmẹ́lẹ́ níyànjú; bẹ́ẹ̀ náà ni kí ẹ máa ṣe sí àwọn tí ó ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn; ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́; ẹ máa mú sùúrù pẹlu gbogbo eniyan.

Tẹsalonika Kinni 5