1. Èmi Paulu, ati Silifanu, ati Timoti, ni à ń kọ ìwé yìí sí ìjọ Tẹsalonika, tíí ṣe ìjọ Ọlọrun Baba ati ti Jesu Kristi Oluwa.
2. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba ati Oluwa Jesu Kristi máa wà pẹlu yín.
3. Ẹ̀yin ará, ó yẹ kí á máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nígbà gbogbo nítorí yín. Ó tọ́ bẹ́ẹ̀ nítorí pé igbagbọ yín ń tóbi sí i, ìfẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan yín sí ara yín sì ń pọ̀ sí i.
4. Àwa fúnra wa ń fọ́nnu nípa yín láàrin àwọn ìjọ Ọlọrun. À ń ròyìn ìfaradà ati igbagbọ yín ninu gbogbo inúnibíni ati ìpọ́njú tí ẹ̀ ń faradà.
5. Ìfaradà yín jẹ́ ẹ̀rí ìdájọ́ òdodo Ọlọrun láti kà yín yẹ fún ìjọba rẹ̀ tí ẹ̀ ń tìtorí rẹ̀ jìyà.
6. Nítorí ó tọ́ lójú Ọlọrun láti fi ìpọ́njú san ẹ̀san fún àwọn tí wọn ń pọn yín lójú,
7. ati láti fún ẹ̀yin tí wọn ń pọ́n lójú, ati àwa náà ní ìsinmi, nígbà tí Oluwa wa, Jesu, bá farahàn láti ọ̀run ninu ọwọ́ iná pẹlu àwọn angẹli tí wọ́n jẹ́ alágbára.