12. Àwọn mààlúù yìí bá doríkọ ọ̀nà Beti Ṣemeṣi, wọ́n ń lọ tààrà láì yà sọ́tùn-ún tabi sósì. Wọ́n ń ké bí wọ́n ti ń lọ. Àwọn ọba Filistini maraarun tẹ̀lé wọn títí dé odi Beti Ṣemeṣi.
13. Àwọn ará ìlú Beti ṣemeṣi ń kórè ọkà lọ́wọ́ ní àfonífojì náà, bí wọ́n ti gbójú sókè, wọ́n rí àpótí ẹ̀rí. Inú wọn dùn pupọ pupọ bí wọ́n ti rí i.
14. Nígbà tí kẹ̀kẹ́ ẹrù náà dé ibi oko Joṣua, ará Beti Ṣemeṣi, ó dúró níbẹ̀. Àpáta ńlá kan wà níbẹ̀, àwọn eniyan náà bá gé igi tí wọ́n fi kan kẹ̀kẹ́ ẹrù náà sí wẹ́wẹ́, wọ́n pa mààlúù mejeeji, wọ́n sì fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA.