Nígbà tí kẹ̀kẹ́ ẹrù náà dé ibi oko Joṣua, ará Beti Ṣemeṣi, ó dúró níbẹ̀. Àpáta ńlá kan wà níbẹ̀, àwọn eniyan náà bá gé igi tí wọ́n fi kan kẹ̀kẹ́ ẹrù náà sí wẹ́wẹ́, wọ́n pa mààlúù mejeeji, wọ́n sì fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA.