5. Nígbà tí ọmọkunrin náà rí i pé Saulu kú, òun náà fa idà rẹ̀ yọ, ó ṣubú lé e lórí ó sì kú.
6. Bẹ́ẹ̀ ni Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀ mẹta, ati ọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀ ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ṣe kú ní ọjọ́ kan náà.
7. Nígbà tí àwọn ọmọ ilẹ̀ Israẹli tí wọn ń gbé òdìkejì àfonífojì Jesireeli ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani, gbọ́ pé àwọn ọmọ ogun Israẹli ti sá lójú ogun, ati pé Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀ ti kú; wọ́n sá kúrò ní ìlú wọn. Àwọn ará Filistia bá lọ tẹ̀dó sibẹ.
8. Ní ọjọ́ keji tí àwọn ará Filistia wá láti bọ́ àwọn nǹkan tí ó wà lára àwọn tí wọ́n kú, wọ́n rí òkú Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀ mẹta ní òkè Giliboa.
9. Wọ́n gé orí Saulu, wọ́n sì bọ́ ihamọra rẹ̀, wọ́n ranṣẹ lọ sí gbogbo ilẹ̀ Filistini, pé kí wọ́n kéde ìròyìn ayọ̀ náà fún gbogbo eniyan ati ní gbogbo ilé oriṣa wọn.