21. Dafidi lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn igba (200) eniyan tí àárẹ̀ mú pupọ, tí wọn kò lè kọjá odò, ṣugbọn tí wọ́n dúró lẹ́yìn odò Besori; àwọn náà wá pàdé Dafidi ati àwọn tí wọ́n bá a lọ. Dafidi sì kí wọn dáradára.
22. Àwọn tí wọ́n jẹ́ eniyan burúkú ati òǹrorò láàrin àwọn tí wọ́n bá Dafidi lọ ní, “Nítorí pé wọn kò bá wa lọ, a kò ní fún wọn ninu ìkógun wa tí a gbà pada, àfi aya ati àwọn ọmọ wọn nìkan ni wọ́n lè gbà.”
23. Ṣugbọn Dafidi dáhùn pé, “Ẹ̀yin arakunrin mi, ẹ ẹ̀ gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí gbogbo ohun tí OLUWA fifún wa. Òun ni ó pa wá mọ́ tí ó sì fún wa ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọmọ ogun tí wọ́n dojú ìjà kọ wá.
24. Kò sí ẹni tí yóo fara mọ́ àbá yín yìí. Gbogbo wa ni a óo jọ pín ìkógun náà dọ́gba-dọ́gba, ati àwọn tí ó lọ ati àwọn tí ó dúró ti ẹrù.”
25. Láti ọjọ́ náà ni ó ti sọ ọ́ di òfin ati ìlànà ní Israẹli, títí di òní olónìí.
26. Nígbà tí Dafidi pada dé Sikilagi, ó fi ẹ̀bùn ranṣẹ sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olórí Juda; ó mú ninu ìkógun náà, ó ní, “Ẹ̀bùn yín nìyí lára ìkógun tí a kó láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀tá OLUWA.”
27. Ó fi ranṣẹ sí àwọn tí wọ́n wà ní Bẹtẹli, ati àwọn tí wọ́n wà ní Ramoti ti Nẹgẹbu, ati Jatiri;
28. ati àwọn tí wọ́n wà ní Aroeri, Sifimoti, ati ní Eṣitemoa;
29. ní Rakali, ní àwọn ìlú Jerameeli, àwọn ìlú Keni,
30. ní Homa, Boraṣani, ati ní Ataki,
31. ní Heburoni ati ní gbogbo ìlú tí Dafidi ati àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ti rìn kiri.