13. Gẹ́gẹ́ bí òwe ìgbà àtijọ́ ti wí, àwọn eniyan burúkú a máa hùwà burúkú, ṣugbọn n kò ní ṣe ọ́ ní ibi kan.
14. Ta ni ìwọ odidi ọba Israẹli ń gbìyànjú láti pa? Ta ni ò ń lépa? Ṣé òkú ajá lásán! Eṣinṣin lásánlàsàn!
15. Kí OLUWA dájọ́ láàrin èmi pẹlu rẹ, kí ó gba ọ̀rọ̀ náà yẹ̀wò, kí ó gbèjà mi, kí ó sì gbà mí, lọ́wọ́ rẹ.”
16. Nígbà tí Dafidi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, Saulu dáhùn pé, “Ṣé ohùn rẹ ni mò ń gbọ́, Dafidi ọmọ mi?” Saulu sì bẹ̀rẹ̀ sí sọkún.
17. Ó wí fún Dafidi pé, “Eniyan rere ni ọ́, èmi ni eniyan burúkú, nítorí pé oore ni ò ń ṣe mí, ṣugbọn èmi ń ṣe ọ́ ní ibi.
18. Lónìí, o ti fi bí o ti jẹ́ eniyan rere sí mi tó hàn mí, nítorí pé o kò pa mí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA fi mí lé ọ lọ́wọ́.
19. Ǹjẹ́ bí eniyan bá rí ọ̀tá rẹ̀, ó lè jẹ́ kí ó lọ ní alaafia? Kí OLUWA bukun ọ nítorí ohun tí o ṣe fún mi lónìí.
20. Nisinsinyii, mo mọ̀ dájú pé o óo jọba ilẹ̀ Israẹli, ìjọba Israẹli yóo sì tẹ̀síwájú nígbà tìrẹ.
21. Nítorí náà, búra fún mi pé o kò ní pa ìdílé mi run lẹ́yìn mi, ati pé o kò ní pa orúkọ mi rẹ́ ní ìdílé baba mi.”