1. Nígbà tí Saulu bá àwọn ará Filistia jagun tán, wọ́n sọ fún un pé Dafidi wà ní aṣálẹ̀ Engedi.
2. Saulu mú ẹgbẹẹdogun (3,000) akọni ọmọ ogun lára àwọn ọmọ ogun Israẹli, wọ́n lọ láti wá Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ ní orí àwọn àpáta ewúrẹ́ ìgbẹ́.
3. Nígbà tí Saulu dé ibi tí àwọn agbo aguntan kan wà lẹ́bàá ọ̀nà, ó rí ihò àpáta ńlá kan lẹ́bàá ibẹ̀, ó sì wọ inú rẹ̀ lọ láti sinmi. Ihò náà jẹ́ ibi tí Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ farapamọ́ sí.
4. Àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ Dafidi sọ fún un pé, “Òní gan-an ni ọjọ́ tí OLUWA ti sọ fún ọ nípa rẹ̀, pé òun yóo fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́, kí o lè ṣe é bí ó ti wù ọ́.” Dafidi bá yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ sí ibi tí Saulu wà, ó sì gé etí aṣọ rẹ̀.
5. Lẹ́yìn náà, ọkàn Dafidi bẹ̀rẹ̀ sí dá a lẹ́bi nítorí pé ó gé etí aṣọ Saulu.