Samuẹli Kinni 23:11-24 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Ǹjẹ́ àwọn alàgbà Keila yóo fà mí lé Saulu lọ́wọ́? Ṣe Saulu yóo wá gẹ́gẹ́ bí mo ti gbọ́? Jọ̀wọ́, OLUWA Ọlọrun Israẹli, fún mi ní èsì.”OLUWA sì dáhùn pé, “Saulu yóo wá.”

12. Dafidi tún bèèrè pé, “Ǹjẹ́ àwọn alàgbà Keila yóo fà mí lé e lọ́wọ́?”OLUWA dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, wọn yóo fà ọ́ lé e lọ́wọ́.”

13. Nítorí náà, Dafidi ati ẹgbẹta (600) àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ kúrò ní Keila lẹsẹkẹsẹ. Nígbà tí Saulu gbọ́ pé Dafidi ti kúrò ní Keila, kò lọ gbógun ti Keila mọ́.

14. Dafidi bá ń lọ gbé orí òkè kan tí ó ṣe é farapamọ́ sí ní aṣálẹ̀ Sifi. Saulu ń wá a lojoojumọ láti pa á, ṣugbọn Ọlọrun kò fi Dafidi lé e lọ́wọ́.

15. Ẹ̀rù ba Dafidi nítorí pé Saulu ń wá ọ̀nà láti pa á.Dafidi ń gbé aṣálẹ̀ Sifi ni Horeṣi.

16. Jonatani ọmọ Saulu wá a lọ sibẹ ó sì fi ọ̀rọ̀ Ọlọrun gbà á níyànjú.

17. Ó sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, nítorí pé ọwọ́ Saulu, baba mi, kò ní tẹ̀ ọ́. O óo jọba lórí Israẹli, n óo sì jẹ́ igbákejì rẹ.”

18. Àwọn mejeeji dá majẹmu níwájú OLUWA; Dafidi dúró ní Horeṣi, Jonatani sì pada sílé.

19. Àwọn ará Sifi kan lọ sọ́dọ̀ Saulu ní Gibea, wọ́n sọ fún un pé, “Dafidi sá pamọ́ sáàrin wa ní Horeṣi ní orí òkè Hakila tí ó wà ní ìhà gúsù Jeṣimoni.

20. Nítorí náà, wá sọ́dọ̀ wa nígbà tí o bá fẹ́, a óo sì fà á lé ọ lọ́wọ́.”

21. Saulu dáhùn pé, “OLUWA yóo bukun yín nítorí pé ẹ káàánú mi.

22. Ẹ lọ nisinsinyii kí ẹ sì tún ṣe ìwádìí dáradára nípa ibi tí ó wà, ati ẹni tí ó rí i níbẹ̀; nítorí mo gbọ́ pé alárèékérekè ẹ̀dá ni Dafidi.

23. Ẹ mọ gbogbo ibi tíí máa ń sá pamọ́ sí dájúdájú, kí ẹ sì wá ròyìn fún mi. N óo ba yín lọ; bí ó bá wà níbẹ̀, n óo wá a kàn, bí ó bá tilẹ̀ wà láàrin ẹgbẹẹgbẹrun eniyan ilẹ̀ Juda.”

24. Wọ́n bá pada sí Sifi ṣáájú Saulu. Ṣugbọn Dafidi ati àwọn ọkunrin rẹ̀ ti wà ní aṣálẹ̀ Maoni tí ó wà ní Araba lápá ìhà gúsù Jeṣimoni.

Samuẹli Kinni 23