15. Ǹjẹ́ èyí ha ni ìgbà àkọ́kọ́ tí mo bá a ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ Ọlọ́run? Rárá o! Nítorí náà kí ọba má ṣe ka ẹ̀sùn kankan sí èmi ati ìdílé baba mi lẹ́sẹ̀, nítorí pé, èmi iranṣẹ rẹ, kò mọ nǹkankan nípa ọ̀tẹ̀ tí Dafidi dì sí ọ.”
16. Ọba dáhùn pé, “Ahimeleki, ìwọ ati ìdílé baba rẹ yóo kú.”
17. Ọba bá pàṣẹ fún àwọn ọmọ ogun tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ pa àwọn alufaa OLUWA nítorí pé wọ́n wà lẹ́yìn Dafidi, wọ́n mọ̀ pé ó ń sá lọ, wọn kò sì sọ fún mi.” Ṣugbọn àwọn ọmọ ogun náà kọ̀ láti pa àwọn alufaa OLUWA.
18. Ọba bá pàṣẹ fún Doegi pé, “Ìwọ, lọ pa wọ́n.” Doegi ará Edomu sì pa alufaa marunlelọgọrin, tí ń wọ aṣọ efodu.
19. Saulu pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn tí wọn ń gbé Nobu, ìlú àwọn alufaa, atọkunrin atobinrin, àtọmọdé, àtọmọ ọwọ́, ati mààlúù, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ati aguntan, wọ́n sì pa gbogbo wọn.
20. Ṣugbọn Abiatari, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Ahimeleki sá àsálà, ó sì lọ sọ́dọ̀ Dafidi.
21. Ó sọ fún un bí Saulu ṣe pa àwọn alufaa OLUWA.
22. Dafidi dá a lóhùn pé, “Nígbà tí mo ti rí Doegi níbẹ̀ ní ọjọ́ náà ni mo ti fura pé yóo sọ fún Saulu. Nítorí náà, ẹ̀bi ikú àwọn eniyan rẹ wà lọ́rùn mi.
23. Dúró tì mí, má sì ṣe bẹ̀rù, nítorí pé Saulu tí ó fẹ́ pa ọ́, fẹ́ pa èmi pàápàá, ṣugbọn o óo wà ní abẹ ààbò níbí.”