Saulu pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn tí wọn ń gbé Nobu, ìlú àwọn alufaa, atọkunrin atobinrin, àtọmọdé, àtọmọ ọwọ́, ati mààlúù, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ati aguntan, wọ́n sì pa gbogbo wọn.