36. Ó sọ fún ọmọ náà pé, “Sáré lọ wá àwọn ọfà tí mo ta wá.” Bí ọmọ náà ti ń sáré lọ, Jonatani ta ọfà siwaju rẹ̀.
37. Nígbà tí ọmọ náà dé ibi tí ọfà náà balẹ̀ sí, Jonatani pè é, ó ní, “Ọfà náà wà níwájú rẹ,”
38. Jonatani tún sọ fún un pe, “Yára má ṣe dúró.” Ọmọ náà ṣa àwọn ọfà náà, ó sì pada sọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀,
39. kò mọ nǹkankan; Jonatani ati Dafidi nìkan ni wọ́n mọ ìtumọ̀ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀.
40. Jonatani kó àwọn ohun ìjà rẹ̀ fún ọmọ náà pé kí ó kó wọn lọ sílé.