6. OLUWA ni ó lè pa eniyan tán,kí ó sì tún jí i dìde;òun ni ó lè múni lọ sinu isà òkú,tí ó sì tún lè fani yọ kúrò níbẹ̀.
7. OLUWA ni ó lè sọni di aláìní,òun náà ni ó sì lè sọ eniyan di ọlọ́rọ̀.Òun ni ó ń gbéni ga,òun náà ni ó sì ń rẹ eniyan sílẹ̀.
8. OLUWA ń gbé talaka dìde láti ipò ìrẹ̀lẹ̀;ó ń gbé aláìní dìde láti inú òṣì rẹ̀,láti mú wọn jókòó pẹlu àwọn ọmọ ọba,kí wọ́n sì wà ní ipò ọlá.Nítorí pé òun ni ó ni àwọn ìpìlẹ̀ ayé,òun ni ó sì gbé ayé kalẹ̀ lórí wọn.
9. “Yóo pa àwọn olóòótọ́ tí wọ́n jẹ́ tirẹ̀ mọ́,ṣugbọn yóo mú kí àwọn eniyan burúkú parẹ́ ninu òkùnkùn;nítorí pé, kì í ṣe nípa agbára eniyan, ni ẹnikẹ́ni lè fi ṣẹgun.