34. Ní ọjọ́ kan náà ni àwọn ọmọ rẹ mejeeji, Hofini ati Finehasi, yóo kú. Èyí ni yóo jẹ́ àmì fún ọ pé gbogbo ohun tí mo sọ ni yóo ṣẹ.
35. N óo yan alufaa mìíràn fún ara mi, tí yóo ṣe olóòótọ́ sí mi, tí yóo sì ṣe gbogbo ohun tí mo bá fẹ́ kí ó ṣe. N óo fi ìdí ìdílé rẹ̀ múlẹ̀, yóo sì máa ṣe iṣẹ́ alufaa níwájú ẹni àmì òróró mi.
36. Èyíkéyìí tí ó bá wà láàyè ninu arọmọdọmọ rẹ yóo máa tọ alufaa yìí lọ láti tọrọ owó ati oúnjẹ lọ́wọ́ rẹ̀. Ẹ̀bẹ̀ ni yóo sì máa bẹ̀, pé kí ó fi òun sí ipò alufaa kí òun baà lè máa rí oúnjẹ jẹ.”