1. Saulu sọ fún ọmọ rẹ̀ Jonatani ati gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé kí wọ́n pa Dafidi. Ṣugbọn Jonatani fẹ́ràn Dafidi lọpọlọpọ.
2. Ó sì sọ fún Dafidi pé, “Baba mi fẹ́ pa ọ́, nítorí náà fi ara pamọ́ sí ibi kọ́lọ́fín kan lọ́la, kí o má ṣe wá sí gbangba.
3. N óo dúró pẹlu baba mi ní orí pápá lọ́la níbi tí o bá farapamọ́ sí, n óo sì bá a sọ̀rọ̀ nípa rẹ, ohunkohun tí mo bá sì gbọ́ lẹ́nu rẹ̀, n óo sọ fún ọ.”