16. Odidi ogoji ọjọ́ ni Goliati fi pe àwọn ọmọ ogun Israẹli níjà ní àràárọ̀ ati ìrọ̀lẹ́ ìrọ̀lẹ́.
17. Ní ọjọ́ kan, Jese sọ fún Dafidi pé, “Jọ̀wọ́, mú ìwọ̀n efa àgbàdo yíyan kan, ati burẹdi mẹ́wàá yìí lọ fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ ní ibùdó ogun.
18. Mú wàrà sísè mẹ́wàá yìí lọ́wọ́ fún olórí ogun ikọ̀ wọn, kí o sì bá mi wo alaafia àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ, kí o gba nǹkankan bọ̀ lọ́dọ̀ wọn tí yóo fihàn mí pé alaafia ni wọ́n wà.”
19. Saulu ọba, ati àwọn ẹ̀gbọ́n Dafidi ati àwọn ọmọ ogun yòókù wà ní àfonífojì Ela níbi tí wọ́n ti ń bá àwọn Filistini jà.
20. Dafidi dìde ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, ó fi ẹnìkan ṣọ́ agbo ẹran rẹ̀, ó mú oúnjẹ náà, ó sì lọ gẹ́gẹ́ bí Jese ti pàṣẹ fún un. Ó dé ibùdó ogun ní àkókò tí àwọn ọmọ ogun ń lọ sójú ogun, wọ́n ń hó ìhó ogun.
21. Àwọn ọmọ ogun Israẹli ati ti Filistini dúró ní ipò wọn, wọ́n ń wo ara wọn.