Samuẹli Kinni 12:11-17 BIBELI MIMỌ (BM)

11. OLUWA bá rán Jerubaali ati Baraki, ati Jẹfuta ati èmi, Samuẹli, láti gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín káàkiri, ó sì jẹ́ kí ẹ wà ní alaafia.

12. Ṣugbọn nígbà tí ẹ rí i pé Nahaṣi, ọba Amoni fẹ́ gbé ogun tì yín, ẹ kọ OLUWA lọ́ba, ẹ wí fún mi pé, ẹ fẹ́ ọba tí yóo jẹ́ alákòóso yín.

13. “Ọba tí ẹ bèèrè fún náà nìyí, ẹ̀yin ni ẹ bèèrè rẹ̀, OLUWA sì ti fun yín nisinsinyii.

14. Bí ẹ bá bẹ̀rù OLUWA, tí ẹ̀ ń sìn ín, tí ẹ̀ ń gbọ́ tirẹ̀, tí ẹ sì ń pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, tí ẹ̀yin ati ọba tí ń ṣe àkóso yín bá ń tẹ̀lé àwọn ìlànà OLUWA Ọlọrun yín, ohun gbogbo ni yóo máa lọ déédé fun yín.

15. Ṣugbọn bí ẹ kò bá gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ kò sì pa òfin rẹ̀ mọ́, yóo dojú ìjà kọ ẹ̀yin ati ọba yín.

16. Nítorí náà, ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ wo iṣẹ́ ńlá tí OLUWA yóo ṣe.

17. Àkókò ìkórè ọkà nìyí, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? N óo gbadura, OLUWA yóo sì jẹ́ kí ààrá sán, kí òjò sì rọ̀. Nígbà tí èyí bá ṣẹlẹ̀, ẹ óo mọ̀ pé bíbèèrè tí ẹ bèèrè fún ọba, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni ẹ dá sí OLUWA.”

Samuẹli Kinni 12