24. Àwọn mìíràn tí wọ́n tún jẹ́ ara “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni” náà nìwọ̀nyí: Asaheli arakunrin Joabu, ati Elihanani, ọmọ Dodo, ará Bẹtilẹhẹmu.
25. Ṣama ati Elika, àwọn mejeeji jẹ́ ará Harodu;
26. Helesi, ará Paliti, Ira, ọmọ Ikeṣi, ará Tekoa;
27. Abieseri, ará Anatoti, ati Mebunai, ará Huṣa;
28. Salimoni, ará Ahohi, ati Maharai, ará Netofa;
29. Helebu, ọmọ Baana, tí òun náà jẹ́ ará Netofa, ati Itai, ọmọ Ribai, ará Gibea, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini;
30. Bẹnaya ará Piratoni ati Hidai ará ẹ̀bá àwọn odò Gaaṣi;
31. Abialiboni ará Araba, ati Asimafeti ará Bahurimu;
32. Eliaba, ará Ṣaaliboni, àwọn ọmọ Jaṣeni, ati Jonatani;
33. Ṣama, ará Harari, Ahiamu, ọmọ Ṣarari, ará Harari;
34. Elifeleti, ọmọ Ahasibai, ará Maaka, Eliamu, ọmọ Ahitofẹli, ará Gilo;
35. Hesiro, ará Kamẹli, Paarai, ará Abiti;
36. Igali, ọmọ Natani, ará Soba, Bani, ará Gadi;
37. Seleki, ará Amoni, Naharai, ará Beeroti, tí ó máa ń ru ihamọra Joabu, ọmọ Seruaya.