1. Nígbà tí OLUWA gba Dafidi lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ati lọ́wọ́ Saulu, Dafidi kọ orin yìí sí OLUWA pé:
2. “OLUWA ni àpáta mi,ààbò mi, ati olùgbàlà mi;
3. Ọlọrun mi, àpáta mi,ọ̀dọ̀ ẹni tí mo sá pamọ́ sí.Àpáta mi ati ìgbàlà mi,ààbò mi ati ibi ìpamọ́ mi,olùgbàlà mi, ìwọ ni o gbà mí lọ́wọ́ ìwà ipá.
4. Mo ké pe OLUWA, ẹni tí ìyìn yẹ,Ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.
5. “Ikú yí mi káàkiri, bí ìgbì omi;ìparun sì bò mí mọ́lẹ̀ bíi ríru omi;
6. isà òkú ya ẹnu sílẹ̀ dè mí,ewu ikú sì dojú kọ mí.