Samuẹli Keji 22:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí OLUWA gba Dafidi lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ati lọ́wọ́ Saulu, Dafidi kọ orin yìí sí OLUWA pé:

2. “OLUWA ni àpáta mi,ààbò mi, ati olùgbàlà mi;

3. Ọlọrun mi, àpáta mi,ọ̀dọ̀ ẹni tí mo sá pamọ́ sí.Àpáta mi ati ìgbàlà mi,ààbò mi ati ibi ìpamọ́ mi,olùgbàlà mi, ìwọ ni o gbà mí lọ́wọ́ ìwà ipá.

Samuẹli Keji 22