1. Àwọn kan lọ sọ fún Joabu pé, ọba ń sọkún, ó sì ń ṣọ̀fọ̀ Absalomu.
2. Nítorí náà, ìṣẹ́gun ọjọ́ náà pada di ìbànújẹ́ fún gbogbo àwọn eniyan; nítorí wọ́n gbọ́ pé ọba ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀.
3. Àwọn ọmọ ogun náà yọ́ wọ ìlú jẹ́ẹ́, bí ẹni pé wọ́n sá lójú ogun, tí ìtìjú sì mú wọn.