1. Lẹ́yìn èyí, Absalomu wá kẹ̀kẹ́ ogun kan, ati àwọn ẹṣin, ati aadọta ọkunrin tí wọn yóo máa sáré níwájú rẹ̀.
2. A máa jí ní òwúrọ̀ kutukutu, a sì dúró ní ẹ̀bá ọ̀nà, ní ẹnu ibodè ìlú. Nígbàkúùgbà tí ẹnikẹ́ni bá ń mú ẹjọ́ bọ̀ wá sọ́dọ̀ ọba, Absalomu á pe olúwarẹ̀ sọ́dọ̀, á bi í pé, “Níbo ni o ti wá?” Lẹ́yìn ìgbà tí ẹni náà bá sọ inú ẹ̀yà tí òun ti wá fún Absalomu tán,
3. Absalomu á wí fún un pé, “Wò ó, ẹjọ́ rẹ tọ́, o sì jàre, ṣugbọn ọba kò yan ẹnikẹ́ni gẹ́gẹ́ bí aṣojú rẹ̀, láti máa gbọ́ irú ẹjọ́ báyìí.”
4. Absalomu á tún wá fi kún un pé, “A! Bí wọ́n bá fi mí ṣe adájọ́ ní ilẹ̀ yìí ni, bí ẹnikẹ́ni bá ní èdè-àìyedè kan pẹlu ẹlòmíràn, tabi tí ẹnìkan bá fẹ́ gba ohun tíí ṣe ẹ̀tọ́ rẹ̀, wọn ìbá máa tọ̀ mí wá, ǹ bá sì máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́ fún wọn.”
5. Bí ẹnikẹ́ni bá súnmọ́ Absalomu láti wólẹ̀, kí ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, Absalomu á tètè na ọwọ́ sí i, á gbá a mú, a sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu.
6. Bẹ́ẹ̀ ni Absalomu máa ń ṣe sí gbogbo àwọn eniyan Israẹli, tí wọ́n bá kó ẹjọ́ wá sọ́dọ̀ ọba. Nítorí bí ó ti ń ṣe yìí, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n fẹ́ràn rẹ̀.
7. Ní ìparí ọdún kẹrin, Absalomu tọ Dafidi lọ, ó ní, “Kabiyesi, fún mi láàyè kí n lọ sí Heburoni. Mo fẹ́ lọ san ẹ̀jẹ́ kan tí mo jẹ́ fún OLUWA.