Samuẹli Keji 12:5-12 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Nígbà tí Dafidi gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, inú bí i gidigidi sí ọkunrin ọlọ́rọ̀ náà tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi OLUWA Alààyè búra pé ẹni tí ó dán irú rẹ̀ wò, kíkú ni yóo kú.

6. Ó sì níláti san ìlọ́po mẹrin ọmọ aguntan tí ó gbà pada, nítorí nǹkan burúkú tí ó ṣe, ati nítorí pé kò ní ojú àánú.

7. Natani bá dá Dafidi lóhùn pé, “Ìwọ gan-an ni ẹni náà. Ohun tí OLUWA Ọlọrun Israẹli sì ní kí n wí fún ọ nìyí; ó ní, ‘Mo fi ọ́ jọba lórí Israẹli, mo sì gbà ọ́ kúrò lọ́wọ́ Saulu.

8. Mo fún ọ ní ilé oluwa rẹ ati àwọn aya rẹ̀. Mo fi ọ́ jọba lórí Israẹli ati Juda. Ati pé, bí èyí kò bá tó ọ, ǹ bá fún ọ ní ìlọ́po meji rẹ̀.

9. Kí ló dé tí o fi kẹ́gàn ọ̀rọ̀ OLUWA, tí o sì ṣe nǹkan burúkú yìí níwájú rẹ̀. Ìwọ ni o fi Uraya fún ogun pa; tí o jẹ́ kí àwọn Amoni pa á. Lẹ́yìn náà, o gba aya rẹ̀.

10. Nítorí náà, ogun kò ní kúrò ní ìdílé rẹ títí lae; nítorí pé o ti kẹ́gàn mi, o sì ti gba aya Uraya.

11. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Wò ó! N óo jẹ́ kí ẹnìkan ninu ìdílé rẹ ṣe ibi sí ọ. Ojú rẹ ni yóo ṣe tí n óo fi fi àwọn aya rẹ fún ẹlòmíràn, tí yóo sì máa bá wọn lòpọ̀ ní ọ̀sán gangan.

12. Níkọ̀kọ̀ ni o dá ẹ̀ṣẹ̀ yìí, ṣugbọn níwájú gbogbo Israẹli, ní ọ̀sán gangan, ni n óo ṣe ohun tí mò ń sọ yìí.’ ”

Samuẹli Keji 12