28. kó àwọn ọmọ ogun yòókù jọ, kí o kọlu ìlú náà, kí o sì gbà á fúnra rẹ. N kò fẹ́ gba ìlú náà kí ògo gbígbà rẹ̀ má baà jẹ́ tèmi.”
29. Dafidi bá kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ, ó lọ sí Raba, ó gbógun tì í, ó sì ṣẹgun rẹ̀.
30. Dafidi ṣí adé wúrà orí ọba wọn, adé náà wọ̀n tó ìwọ̀n talẹnti wúrà kan, ó sì ní òkúta olówó iyebíye kan lára, ó sì fi dé orí ara rẹ̀. Dafidi kó ọpọlọpọ àwọn ìkógun mìíràn ninu ìlú náà.
31. Ó bẹ̀rẹ̀ sí kó gbogbo àwọn ará ìlú náà ṣiṣẹ́. Àwọn kan ń lo ayùn, àwọn mìíràn ń lo ọkọ́ onírin, ati àáké onírin, àwọn mìíràn sì ń gé bulọọku, wọ́n ń sun ún. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe sí àwọn ará ìlú Amoni yòókù. Lẹ́yìn náà, òun ati àwọn eniyan rẹ̀ pada sí Jerusalẹmu.