12. Alaafia ni wọn yóo fi gbin èso wọn, àjàrà wọn yóo so jìnwìnnì, òjò yóo rọ̀, ilẹ̀ yóo sì mú èso jáde. Àwọn eniyan mi tí ó ṣẹ́kù ni yóo sì ni gbogbo nǹkan wọnyi.
13. Ẹ̀yin ilé Juda ati ilé Israẹli, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé orúkọ yín ni àwọn eniyan fi ń ṣépè lé àwọn mìíràn tẹ́lẹ̀, ṣugbọn nisinsinyii, n óo gbà yín, ẹ óo sì di orísun ibukun. Nítorí náà, ẹ mọ́kànle, ẹ má bẹ̀rù.”
14. OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Gẹ́gẹ́ bí mo ti pinnu láti ṣe yín ní ibi nígbà tí àwọn baba yín mú mi bínú, tí n kò sì yí ìpinnu mi pada,
15. bẹ́ẹ̀ ni mo tún pinnu nisinsinyii láti ṣe ẹ̀yin ará Jerusalẹmu ati àwọn ará ilé Juda ní rere. Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù.