1. OLUWA àwọn ọmọ ogun tún bá mi sọ̀rọ̀ pé
2. Òun fẹ́ràn àwọn ará Sioni; nítorí náà ni inú òun ṣe ru sí àwọn ọ̀tá wọn.
3. Ó ní, òun óo pada sí Sioni, òun óo máa gbé Jerusalẹmu, a óo máa pe Jerusalẹmu ní ìlú olóòótọ́, òkè OLUWA àwọn ọmọ ogun, ati òkè mímọ́.
4. Àwọn arúgbó lọkunrin, lobinrin, tí wọn ń tẹ̀pá yóo jókòó ní ìgboro Jerusalẹmu,
5. ìta ati òpópónà yóo sì kún fún àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin tí wọn ń ṣeré.
6. OLUWA àwọn ọmọ ogun ní bí eléyìí bá jẹ́ ohun ìyanu lójú àwọn eniyan yòókù, ǹjẹ́ ó yẹ kí ó jẹ́ ohun ìyanu lójú òun náà?
7. Ó ní òun óo gba àwọn eniyan òun là láti orílẹ̀-èdè tí ó wà ní ìlà oòrùn ati ti ìwọ̀ rẹ̀,
8. òun óo mú wọn pada wá sí Jerusalẹmu láti máa gbébẹ̀; wọn óo jẹ́ eniyan òun, òun náà óo sì jẹ́ Ọlọrun wọn, lóòótọ́ ati lódodo.