Sakaraya 7:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọjọ́ kẹrin oṣù kẹsan-an, tíí ṣe oṣù Kisilefi, ní ọdún kẹrin ìjọba Dariusi, ni OLUWA rán mi níṣẹ́ yìí.

2. Àwọn ará Bẹtẹli rán Ṣareseri ati Regemumeleki ati gbogbo àwọn eniyan wọn lọ sí ilé OLUWA; wọ́n lọ wá ojurere OLUWA,

3. wọn sì lọ bèèrè lọ́wọ́ àwọn alufaa ilé OLUWA, àwọn ọmọ ogun ati àwọn wolii pé, “Nígbà wo ni a óo dẹ́kun láti máa ṣọ̀fọ̀, ati láti máa gbààwẹ̀ ní oṣù karun-un bí a ti ń ṣe láti ọpọlọpọ ọdún sẹ́yìn?”

4. OLUWA àwọn ọmọ ogun bá rán mi pé,

5. “Sọ fún gbogbo àwọn eniyan ilẹ̀ náà ati àwọn alufaa pé, nígbà tí ẹ̀ ń gbààwẹ̀, tí ẹ sì ń ṣọ̀fọ̀ ní oṣù karun-un ati oṣù keje fún odidi aadọrin ọdún, ṣé èmi ni ẹ̀ ń gbààwẹ̀ fún?

6. Tabi nígbà tí ẹ̀ ń jẹ tí ẹ sì ń mu, kì í ṣe ara yín ni ẹ̀ ń jẹ tí ẹ̀ ń mu fún?”

7. Nígbà tí nǹkan fi ń dára fún Jerusalẹmu, tí eniyan sì pọ̀ níbẹ̀, ati àwọn ìlú agbègbè tí ó yí i ká, ati àwọn ìlú ìhà gúsù ati ti ẹsẹ̀ òkè ní ìwọ̀ oòrùn; ṣebí àwọn wolii OLUWA ti sọ nǹkan wọnyi tẹ́lẹ̀?

8. OLUWA tún rán Sakaraya kí ó sọ fún wọn pé,

9. “Ẹ gbọdọ̀ máa dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́, kí ẹ sì fi àánú ati ìyọ́nú hàn sí ara yín.

10. Ẹ má máa fi ìyà jẹ àwọn opó, tabi àwọn aláìníbaba, tabi àwọn àlejò tí wọn ń gbé ààrin yín, tabi àwọn aláìní. Ẹ má máa gbèrò ibi sí ẹnikẹ́ni.”

Sakaraya 7