1. Mo tún gbé ojú sókè, mo rí kẹ̀kẹ́ ogun mẹrin tí ń bọ̀ láàrin òkè meji; òkè idẹ ni àwọn òkè náà.
2. Àwọn ẹṣin pupa ni wọ́n ń fa kẹ̀kẹ́ ogun àkọ́kọ́, àwọn ẹṣin dúdú ń fa kẹ̀kẹ́ ogun keji,
3. ẹṣin funfun ń fa ẹkẹta, àwọn tí wọn ń fa ẹkẹrin sì jẹ́ kàláńkìnní.
4. Mo bi angẹli náà pé, “Oluwa mi, kí ni ìtumọ̀ ìwọ̀nyí?”
5. Angẹli náà bá dáhùn pé, “Àwọn wọnyi ni wọ́n ń lọ sí igun mẹrẹẹrin ayé lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ara wọn han Ọlọrun ẹlẹ́dàá gbogbo ayé.”
6. Àwọn ẹṣin dúdú ń fa kẹ̀kẹ́ tiwọn lọ sí ìhà àríwá, àwọn ẹṣin funfun ń lọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn, àwọn tí wọ́n jẹ́ kàláńkìnní ń lọ sí ìhà gúsù.
7. Bí àwọn ẹṣin tí wọ́n jẹ́ kàláńkìnní ti jáde, wọ́n ń kánjú láti lọ máa rin ayé ká. Angẹli náà bá pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n lọ; wọ́n sì lọ.
8. Angẹli náà bá ké sí mi, ó ní, “Àwọn ẹṣin tí wọn ń lọ sí ìhà àríwá ti jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀ nípa ibẹ̀.”