Peteru Kinni 3:4-14 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Ṣugbọn kí ẹwà yín jẹ́ ti ọkàn tí kò hàn sóde, ọkàn ìrẹ̀lẹ̀ ati ìwà pẹ̀lẹ́. Èyí ni ẹwà tí kò lè ṣá, èyí tí ó ṣe iyebíye lójú Ọlọrun.

5. Nítorí ní ìgbà àtijọ́ irú ẹwà báyìí ni àwọn aya tí a yà sọ́tọ̀, àwọn tí wọ́n ní ìrètí ninu Ọlọrun, fi ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́. Wọ́n bọ̀wọ̀ fún ọkọ wọn.

6. Irú wọn ni Sara tí ó gbọ́ràn sí Abrahamu lẹ́nu tí ó pè é ní “Oluwa mi.” Ọmọ Sara ni yín, tí ẹ bá ń ṣe dáradára, tí ẹ kò jẹ́ kí nǹkankan bà yín lẹ́rù tabi kí ó mú ìpayà ba yín.

7. Kí ẹ̀yin ọkọ náà máa fi ọgbọ́n bá àwọn aya yín gbé. Ẹ máa bu ọlá fún wọn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí kò lágbára to yín. Ẹ ranti pé wọ́n jẹ́ alábàápín ẹ̀bùn ìyè pẹlu yín. Tí ẹ bá ń ṣe èyí, kò ní sí ìdènà ninu adura yín.

8. Ní gbolohun kan, ẹ ní inú kan sí ara yín. Ẹ ni ojú àánú. Ẹ ní ìfẹ́ sí ara yín. Ẹ máa ṣoore. Ẹ ní ọkàn ìrẹ̀lẹ̀.

9. Ẹ má fi burúkú gbẹ̀san burúkú, tabi kí ẹ fi àbùkù kan ẹni tí ó bá fi àbùkù kàn yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa sọ̀rọ̀ wọn ní rere ni. Irú ìwà tí a ní kí ẹ máa hù nìyí, kí ẹ lè jogún ibukun tí Ọlọrun ṣèlérí fun yín.

10. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé,“Ẹni tí ó bá fẹ́ ìgbé-ayé tí ó wù ú,tí ó fẹ́ rí ọjọ́ tí ó dára,ó níláti kó ara rẹ̀ ni ìjánupẹlu ọ̀rọ̀ burúkú sísọ,kí ó má fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.

11. Ó níláti yipada kúrò ninu ìwà burúkú,kí ó máa hu ìwà rere.Ó níláti máa wá alaafia,kí ó sì máa lépa rẹ̀.

12. Nítorí Oluwa ń ṣọ́ àwọn olódodo,ó sì dẹ etí sí ẹ̀bẹ̀ wọn.Ṣugbọn ojú Oluwa kan síàwọn tí ó ń ṣe burúkú.”

13. Ta ni lè ṣe yín ní ibi tí ẹ bá ní ìtara fún ohun tíí ṣe rere?

14. Ṣugbọn bí ẹ bá tilẹ̀ jìyà nítorí òdodo, ẹ ṣe oríire. Ẹ má bẹ̀rù àwọn tí wọn ń jẹ yín níyà, kí ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín dàrú.

Peteru Kinni 3