Peteru Kinni 2:21-25 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Nítorí ìdí èyí ni a fi pè yín, nítorí Kristi jìyà nítorí yín, ó fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fun yín, pé kí ẹ tẹ̀lé àpẹẹrẹ òun.

22. Ẹni tí kò dẹ́ṣẹ̀, tí a kò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ní ẹnu rẹ̀ rí.

23. Nígbà tí àwọn eniyan kẹ́gàn rẹ̀, kò désì pada; wọ́n jẹ ẹ́ níyà, kò ṣe ìlérí ẹ̀san, ṣugbọn ó fi ọ̀ràn rẹ̀ lé Onídàájọ́ òdodo lọ́wọ́.

24. Òun fúnrarẹ̀ ni ó ru ẹ̀ṣẹ̀ wa lórí igi, kí á baà lè kú sí ẹ̀ṣẹ̀, kí á wà láàyè sí òdodo. Nípa ìnà rẹ̀ ni ẹ fi ní ìmúláradá.

25. Nítorí pé nígbà kan ẹ dàbí aguntan tí ó sọnù. Ṣugbọn nisinsinyii ẹ ti yipada sí olùṣọ́ yín ati alabojuto ọkàn yín.

Peteru Kinni 2