2. Olùfẹ́ mi ti lọ sinu ọgbà rẹ̀,níbi ebè igi turari,ó da ẹran rẹ̀ lọ sinu ọgbà,ó lọ já òdòdó lílì.
3. Olùfẹ́ mi ló ni mí,èmi ni mo sì ni olùfẹ́ mi.Láàrin òdòdó lílì,ni ó ti ń da ẹran rẹ̀.
4. Olùfẹ́ mi, o dára bíi Tirisa.O lẹ́wà bíi Jerusalẹmu,O níyì bíi ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun tí ń gbé ọ̀págun.