Orin Solomoni 6:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Níbo ni olùfẹ́ rẹ lọ,ìwọ, arẹwà jùlọ láàrin àwọn obinrin?Níbo ni olùfẹ́ rẹ yà sí,kí á lè bá ọ wá a?

2. Olùfẹ́ mi ti lọ sinu ọgbà rẹ̀,níbi ebè igi turari,ó da ẹran rẹ̀ lọ sinu ọgbà,ó lọ já òdòdó lílì.

3. Olùfẹ́ mi ló ni mí,èmi ni mo sì ni olùfẹ́ mi.Láàrin òdòdó lílì,ni ó ti ń da ẹran rẹ̀.

Orin Solomoni 6