Orin Solomoni 3:5-10 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Mò ń kìlọ̀ fun yín, ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu,mo fi egbin ati àgbọ̀nrín inú igbó búra,pé, ẹ kò gbọdọ̀ jí olùfẹ́ mi, títí yóo fi wù ú láti jí.

6. Kí ló ń jáde bọ̀ láti inú aṣálẹ̀ yìí,tí ó dàbí òpó èéfín,tí ó kún fún òórùn dídùn òjíá ati turari,pẹlu òórùn dídùn àtíkè àwọn oníṣòwò?

7. Wò ó! Solomoni ni wọ́n ń gbé bọ̀, lórí ìtẹ́ rẹ̀,ọgọta akọni ọkunrin, lára àwọn akọni Israẹli,ni ó yí ìtẹ́ rẹ̀ ká.

8. Gbogbo wọn dira ogun pẹlu idà,akọni sì ni wọ́n lójú ogun.Olukuluku dira pẹlu idà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, nítorí ìdágìrì ọ̀gànjọ́.

9. Igi Lẹbanoni ni Solomoni fi ṣe ìtẹ́ rẹ̀.

10. Ó fi fadaka ṣe àwọn ẹsẹ̀ ìjókòó rẹ̀,ó fi wúrà ṣe ẹ̀yìn rẹ̀,Aṣọ elése-àlùkò tí àwọn ọmọbinrin Jerusalẹmu hun ni ó fi ṣe tìmùtìmù ìjókòó rẹ̀.

Orin Solomoni 3