Wò ó! O dára gan-an ni, olólùfẹ́ mi,ẹwà rẹ pọ̀.Ẹyinjú rẹ dàbí ti àdàbà lábẹ́ ìbòjú rẹ,irun orí rẹ dàbí ọ̀wọ́ ewúrẹ́,tí wọn ń sọ̀kalẹ̀ láti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Gileadi.