8. Mo gbọ́ ohùn olùfẹ́ mi, wò ó! Ó ń bọ̀,ó ń fò lórí àwọn òkè ńlá,ó sì ń bẹ́ lórí àwọn òkè kéékèèké.
9. Olólùfẹ́ mi dàbí egbin,tabi ọ̀dọ́ akọ àgbọ̀nrín.Wò ó! Ó dúró lẹ́yìn ògiri ilé wa,ó ń yọjú lójú fèrèsé,ó ń yọjú níbi fèrèsé kékeré tí ó wà lókè.
10. Olùfẹ́ mi bá mi sọ̀rọ̀, ó wí fún mi pé,“Dìde, olùfẹ́ mi, arẹwà mi,jẹ́ kí á máa lọ.”
11. Àkókò òtútù ti lọ,òjò sì ti dáwọ́ dúró.
12. Àwọn òdòdó ti hù jáde,àkókò orin kíkọ ti tó,a sì ti ń gbọ́ ohùn àwọn àdàbà ní ilẹ̀ wa.
13. Àwọn igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ń so èso,àjàrà tí ń tanná,ìtànná wọn sì ń tú òórùn dídùn jáde.Dìde, olùfẹ́ mi, arẹwà mi,jẹ́ kí á máa lọ.