Orin Dafidi 91:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹni tí ń gbé abẹ́ ààbò Ọ̀gá Ògo,tí ó wà lábẹ́ òjìji Olodumare,

2. yóo wí fún OLUWA pé,“Ìwọ ni ààbò ati odi mi,Ọlọrun mi, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé.”

3. Nítorí yóo yọ ọ́ ninu okùn àwọn pẹyẹpẹyẹati ninu àjàkálẹ̀ àrùn apanirun.

4. Yóo da ìyẹ́ rẹ̀ bò ọ́,lábẹ́ ìyẹ́ apá rẹ̀ ni o óo ti rí ààbò;òtítọ́ rẹ̀ ni yóo jẹ́ asà ati apata rẹ.

5. O ò ní bẹ̀rù ìdágìrì òru,tabi ọfà tí ń fò kiri ní ọ̀sán,

6. tabi àjàkálẹ̀ àrùn tí ń jà kiri ninu òkùnkùn,tabi ìparun tí ń ṣeni lófò ní ọ̀sán gangan.

Orin Dafidi 91