1. OLUWA, tọkàntọkàn ni n óo fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ;n óo ròyìn gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ.
2. N óo yọ̀, inú mi yóo sì máa dùn nítorí rẹ;n óo kọ orin ìyìn orúkọ rẹ, ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ.
3. Nígbà tí àwọn ọ̀tá mi pẹ̀yìndà,wọ́n ṣubú, wọ́n sì parun níwájú rẹ.
4. Nítorí ìwọ ni o fi ìdí ẹ̀tọ́ mi múlẹ̀, tí o sì dá mi láre;ìwọ ni o jókòó lórí ìtẹ́, o sì ṣe ìdájọ́ òdodo.
5. O bá àwọn orílẹ̀-èdè wí,o pa àwọn eniyan burúkú run,o sì pa orúkọ wọn rẹ́ títí lae.
6. O pa àwọn ọ̀tá run patapata, o sọ ìlú wọn di ahoro,o sì sọ wọ́n di ẹni ìgbàgbé.
7. Ṣugbọn OLUWA gúnwà títí lae,ó ti fi ìdí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀ múlẹ̀.
8. Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé,yóo sì fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè.
9. OLUWA ni ààbò fún àwọn tí a ni lára,òun ni ibi ìsádi ní ìgbà ìpọ́njú.