48. Ta ló wà láyé tí kò ní kú?Ta ló lè gba ẹ̀mí ara rẹ̀ lọ́wọ́ agbára isà òkú?
49. OLUWA, níbo ni ìfẹ́ rẹ ìgbàanì tí kì í yẹ̀ wà,tí o búra fún Dafidi pẹlu òtítọ́ rẹ?
50. OLUWA, ranti bí èmi, iranṣẹ rẹ, ti di ẹni yẹ̀yẹ́;ati bí mo ti ń farada ẹ̀gàn àwọn eniyan,
51. OLUWA àwọn ọ̀tá rẹ ń fi ẹni tí o fi àmì òróró yàn ṣe yẹ̀yẹ́,wọ́n sì ń kẹ́gàn ìrìn ẹsẹ̀ rẹ̀.