Orin Dafidi 89:32-42 BIBELI MIMỌ (BM)

32. n óo nà wọ́n lẹ́gba nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,n óo sì nà wọ́n ní pàṣán nítorí àìdára wọn.

33. Ṣugbọn ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ kò ní kúrò lára rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni n kò ní yẹ òtítọ́ mi.

34. N kò ni yẹ majẹmu mi,bẹ́ẹ̀ ni n kò ní yí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ pada.

35. “Níwọ̀n ìgbà tí mo ti fi ìwà mímọ́ mi búra:n kò ní purọ́ fún Dafidi.

36. Arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo máa jọba títí lae,ìtẹ́ rẹ̀ yóo sì máa wà níwájú mi, níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ń yọ.

37. A óo fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ bí òṣùpá títí lae,yóo dúró ṣinṣin níwọ̀n ìgbà tí ojú ọ̀run bá ń bẹ.”

38. Ṣugbọn nisinsinyii inú rẹ ti ru sí ẹni àmì òróró rẹ;o ti ta á nù,o sì ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

39. O ti pa majẹmu tí o bá iranṣẹ rẹ dá tì,o ti ba adé rẹ̀ jẹ́, o ti fi wọ́lẹ̀.

40. O ti wó gbogbo odi rẹ̀;o sì ti sọ ilé ìṣọ́ rẹ̀ di ahoro.

41. Gbogbo àwọn tí ń kọjá lọ ní ń kó o lẹ́rù;ó ti di ẹni ẹ̀gàn lọ́dọ̀ àwọn aládùúgbò rẹ̀.

42. O ti ran àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́;o ti mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ yọ̀ ọ́.

Orin Dafidi 89