1. Tẹ́tí sí mi OLUWA, kí o sì gbọ́ adura mi,nítorí òtòṣì ati aláìní ni mí.
2. Dá ẹ̀mí mi sí nítorí olùfọkànsìn ni mí;gba èmi iranṣẹ rẹ tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ là;ìwọ ni Ọlọrun mi.
3. Ṣàánú mi, OLUWA,nítorí ìwọ ni mò ń kígbe pè tọ̀sán-tòru.
4. Mú inú iranṣẹ rẹ dùn,nítorí ìwọ ni mò ń gbadura sí.
5. Nítorí pé olóore ni ọ́, OLUWA,o máa ń dárí jini;ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀ sí gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́.
6. Fetí sí adura mi, OLUWA,gbọ́ igbe ẹ̀bẹ̀ mi.