11. Jẹ́ kí ìkérora àwọn ìgbèkùn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ;gẹ́gẹ́ bí agbára ńlá rẹ,dá àwọn tí a dájọ́ ikú fún sí.
12. OLUWA, san ẹ̀san ẹ̀gàn tí àwọn aládùúgbò wa gàn ọ́,san án fún wọn ní ìlọ́po meje,
13. Nígbà náà, àwa eniyan rẹ,àní, àwa agbo aguntan pápá rẹ,yóo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ títí lae;a óo sì máa sọ̀rọ̀ ìyìn rẹ láti ìran dé ìran.